My Collection of Yoruba Hymns
Aigbagbo Bila Aigbagbo bila! Temi l'Oluwa Oun o si dide fun igbala mi, Ki n sa ma gbadura, Oun o se 'ranwo: 'Gba Krist' wa lodo mi, ifoya ko si. Bona mi ba su, Oun l'O sa n to mi, Ki n sa gboran sa, Oun o si pese; Biranlowo eda gbogbo ba saki, Oro tenu Re so yo bori dandan. Ife to n fi han, ko je ki n ro pe, Yo fi mi sile ninu wahala; Iranwo ti mo si n ri lojojumo, O n ki mi laya pe emi o la a ja. Emi o se kun tori iponju, Tabi irora? O ti so tele! Mo moro Re pawon ajogun 'gbala, Wo ko le sai koja larin wahala. Eda ko le so kikoro ago T'Olugbala mu kelese le ye; Aye Re tile buru ju temi lo, Jesu ha le jiya, kemi si ma sa. Nje bohun gbogbo ti n sise ire, Adun nikoro, ounje li oogun; Boni tile koro, sa ko ni pe mo, Gbana orin 'segun yio ti dun to! Source: Yoruba Baptist Hymnal #330 Begone, unbelief; my Savior is near, and for my relief will surely appear; by prayer let me wrestle, and he will perform; with Christ in the vessel, I smile at the storm. Th...